Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé
Fẹ́mi Akínṣọlá Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní kúusẹ́ ní ín mórí oníṣẹ́ yá. Bẹ́ẹ̀, aríse ni aríkà, aríkà ni baba ìrègún, n ló díá fún kí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé bó ṣe ń ṣàlàyé àṣeyọrí rẹ̀ ní ààrin ọdún kan, bí ó se ṣọ pé àbọ̀ tọ́ sáwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ tó rán òun níṣẹ́. Mákindé, nígbà tó ń kópa lórí àkànṣe ètò tó ń sàmì ọdún kan ìjọba rẹ lórí àlééfa, ṣọ pé, ìjọba òun ti parí àpapọ̀ iṣẹ́ àkànṣe ojilenigba ó dínkan t'íjọba àná fi sílẹ̀ ni ẹka ètò ẹ̀kọ́. Bákan náà ló fikún un pé, ìjọba òun tún ti dáwọ́ lé àkànṣe iṣẹ́ míràn ní ẹ̀ka náà tó tó méjìdínláàdọ́rin pẹ̀lú àfikún pé òun lo àǹfààní àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kofi-19 láti ṣe àgbéga ẹ̀ka ètò ìlera nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni. "Ó ti pé ọdún kan tí mo gba àkóso ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àsìkò ká ṣeré yàtọ̀, bẹ́ẹ̀ àsìkò ìjíyìn iṣẹ́ ìríjú ẹni yàtọ̀ pẹ̀lú, ọdún 2023 sì ni màá jíyìn iṣẹ́ ìríjú mi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n kó tó di ìgbà náà, ó yẹ ká mọ ibi tí a ti ń bọ̀, ká le...