A ò r'ósù lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Àìkú ní ìtúnu ààwẹ̀.. Ìjọba Saudi
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣè bí a ṣèyí ó wù Ú ni Ọba Ọlọ́run, kò wá ku èèyàn tí yóó bíi pé kín ló dé.
Òṣùpá lé, ẹ ní kò gún, ó ku ẹni tí yóó gòkè tún un se.
Bí Ọlọ́run ṣe fi àjùlọ Rẹ̀ hàn lọ́dún yìí ló bí kí Ìjọba orílẹ̀-èdè Saudi Arabia ó ṣàlàyé ní kíkún ìdí tí wọn kò fi ṣe ìtúnu ààwẹ̀ Ramadan ti ọdún yìí ni àná ọjọ́ Àbámẹ́ta 23/5/2020.
Wọ́n ní òní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù karùn ún, ọjọ́ Àìkú ni ìtúnu ààwẹ̀ Ramadan ti ọdún yìí bọ́sí.
Ìjọba Saudi ṣàlàyé pé àwọn onímọ̀ ojú ọjọ́ kò rí oṣù èyí tí ó ṣe pàtàkì láti fi fòpin sí ààwẹ̀ Ramadan gbígbà nínú ẹ̀sìn àwọn mùsùlùmí.
Ṣaájú ni ọ̀pọ̀ mùsùlùmí ti rò pé ọjọ́ Ẹtì ni ààwẹ̀ lámúláánà yóó wa s'ópin, tí wọ́n yóó sì túnu ní ọjọ́ Àbámẹ́ta
Oṣù wíwò láti ara bí ojú ọjọ́ ṣe rí ṣe pàtàkì kí ààwẹ̀ Ramadan tó bẹ̀rẹ̀ tàbí parí nínú ẹ̀sìn àwọn mùsùlùmí.
Lọ́jọ́ Ẹtì ni àwọn onímọ̀ ojú ọjọ́ ní Saudi Arabia ti sọ pé àwọn kò rí oṣù tó yẹ ki ó fòpin sí ààwẹ̀ ọdún yìí.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ààwẹ̀ Ramadan máa ń jẹ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n.
Ààwẹ̀ ọdún yìí bọ́sí òǹkà ọgbọ̀n ọjọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ mùsùlùmí.
Ààwẹ̀ Ramdan gbígbà pọn dandan fún mùsùlùmí òdodo gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára òpó ẹ̀sìn Islam, yàtọ̀ sí ìrun kíkí, sàká yíyọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Comments
Post a Comment