Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ̀yin lẹ ránmi níṣẹ́, n ò níí fojú u yín gbolẹ̀--Ṣèyí Mákindé
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní kúusẹ́ ní ín mórí oníṣẹ́ yá.
Bẹ́ẹ̀, aríse ni aríkà, aríkà ni baba ìrègún, n ló díá fún kí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé bó ṣe ń ṣàlàyé àṣeyọrí rẹ̀ ní ààrin ọdún kan, bí ó se ṣọ pé àbọ̀ tọ́ sáwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ tó rán òun níṣẹ́.
Mákindé, nígbà tó ń kópa lórí àkànṣe ètò tó ń sàmì ọdún kan ìjọba rẹ lórí àlééfa, ṣọ pé, ìjọba òun ti parí àpapọ̀ iṣẹ́ àkànṣe ojilenigba ó dínkan t'íjọba àná fi sílẹ̀ ni ẹka ètò ẹ̀kọ́.
Bákan náà ló fikún un pé, ìjọba òun tún ti dáwọ́ lé àkànṣe iṣẹ́ míràn ní ẹ̀ka náà tó tó méjìdínláàdọ́rin pẹ̀lú àfikún pé òun lo àǹfààní àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kofi-19 láti ṣe àgbéga ẹ̀ka ètò ìlera nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni.
"Ó ti pé ọdún kan tí mo gba àkóso ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àsìkò ká ṣeré yàtọ̀, bẹ́ẹ̀ àsìkò ìjíyìn iṣẹ́ ìríjú ẹni yàtọ̀ pẹ̀lú, ọdún 2023 sì ni màá jíyìn iṣẹ́ ìríjú mi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n kó tó di ìgbà náà, ó yẹ ká mọ ibi tí a ti ń bọ̀, ká leè mọ bá a ṣe ṣe àṣeyọrí si."
"Mo ti mú ìlérí mi ṣẹ láti parí gbogbo iṣẹ́ àṣepatì tí ìjọba tó kọjá lọ ti ṣe láti ọdún 2011, tí n kò sì fi ìmọ tara ẹni nìkan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun míràn, nínú ọdún yìí nìkan, iṣẹ́ òjìlé nígba ó din mẹ́rin la dáwọ́ lé."
Mákindé tún tẹ̀síwájú pé, àyípadà rere ti ń bá owó tí ìjọba Ọ̀yọ́ ń pa wọlé lábẹ́lé, ó sì ti di ìrọ̀rùn láti gba ìwé àṣẹ èmi ni mo nilẹ̀ báyìí, t'óun sì tún ṣe àtúnṣe àwọn ojú pópó tó ti bàjẹ́."
Gómìnà Mákindé ní òun mọ rírí àtìlẹ́yìn àti ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nínú òun.
Ó ní àdúrà wọn ló ń gbé òun ró, bẹ́ẹ̀ ló mú un dáwọn lójú pé, pẹ̀lú àánú Ọlọ́run, òun kò níí jáwọn kulẹ̀
Comments
Post a Comment