A ò setán àti f'ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sòfò, ẹ má tì wá lọ́pọn pọ̀-ọ́n -- Ìjọba àpapọ̀




Fẹ́mi Akínṣọlá

Mínísítà kékeré fún ètò ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà, Emeka Nwajiuba, sọ pé Orílẹ̀ yìí kò setán láti fi ìlera àwọn ọmọdé sínú ewu nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣí iléèwé padà.

Ọ̀gbẹ́ni Nwajiuba ti kò sọ pàtó ọjọ́ tí àwọn ọmọ yóó wọlé padà, sọ pé "Ó di ìgbà tí a bá tó ó ní ìdánilójú pé àwọn ọmọdé lè lọ síléèwé, padà sílé lálàáfíà, láì kó arun Kofi-19 padà sílé, la tó ó setán".

Mínísítà sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tí ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ìtànkálẹ̀ àrùn Kofi-19 ń bá àwọn akọròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́rú, ọjọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta.

Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí wáyé gẹ́gẹ́ bí èsì fún àwọn òbí kan ní Nàìjíríà, tó ń bèèrè pé nígbàwo ni ìjọba yóó ṣí iléèwé padà.

Ọ̀gbẹ́ni Nwajiuba sọ pé iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ yóó gbé ìlànà jáde lórí bí nǹkan yóó ṣe lọ, tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá padà síléèwé.

"Fún àwọn iléèwé girama, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn lè padà síléèwé, láti lè parí ìdánwò wọn, kí wọ́n ó sì tún padà lọ̀ ọ́ jókòó sílé.

"Bákan náà ni aó mú àdínkù bá iye akẹ́kọ̀ọ́  tí yóó wà ní kíláàsì kọ̀ọ̀kan. Èyí ṣeéṣe kó túmọ̀ sí pé ètò ẹ̀kọ́ yóó pín sí Ìlànà òwúrọ̀ àti ọ̀sán, láti le tẹ̀lé Ìlànà títakété síra ẹni."

Mínísítà tún sọ pé àwọn ń gbèrò láti fín òògùn apakòkòrò sí àwọn iléèwé ṣaájú  ìwọlé padà.

Nínú ọ̀rọ̀  tiẹ̀, Alága ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá fún arun Kofi-19, Boss Mustapha, sọ pé "kí àwọn ìpínlẹ̀, àti Ìjọba ìbílẹ̀ ó ṣe gbogbo ètò tó yẹ", kí ètò ẹ̀kọ́ le tètè bẹ̀rẹ̀ padà nínú ìlera pípé.

Ó sọ pé Ìjọba "kò setán láti fi àwọn ọmọ wa tọrẹ fún àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ yìí".

Comments