Họ́wù ! Ààfáà, o kò lè gb'ọ́mọ pínísín yìí níyàwó--- ilé ejọ fọnmú
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní bá a se é se nílẹ̀ yìí, èèwọ̀ ibòmíìn ni , ìdálùú ǹ ṣèlú, eégún ní ín gbowó o bodè níbìkan ló díá fún bí ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ tó ní se pẹ̀lú ìdílé ní ìlú Akure ti pinwọ́ọ Ààfáà tó ìgbìyànjú àti fẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rindinlógún sílé bí ìyàwó rẹ̀ kẹsàn án .
Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta tó gbédájọ́ náà, ti adájọ́ Aderemi Adegoroye darí rẹ̀ kalẹ̀ ti pàṣẹ pé kí wọ́n dá ọmọ ọ̀hún padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀.
Ọdún 2019 ni Ààfáà náà, Yusuf lateef ti kọ́ gbìyànjú láti fẹ́ ọmọdé ọ̀hún nígbà tó ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ girama, ṣùgbọ́n ìgbìyànjú rẹ̀ bọ́rẹ́lẹ̀ .
Kò pẹ́ sí i tí ọmọ náà pé ẹni ọdún mẹ́rindinlógún tí Ààfáà ọ̀hún mú ọjọ́ ìgbéyàwó pẹ̀lú u màjèsìn tí à n ṣọ̀rọ̀
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ọmọ ọ̀hún ṣá kúrò nílé ṣaájú ọjọ́ ìgbéyàwó náà.
Lẹ́yìn ọ̀ rẹyìn, iléeṣẹ́ Ìjọba ìpínlẹ̀ Òǹdó tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin dá sí ọ̀rọ̀
Ìléeṣẹ́ náà pé àwọn òbí ọmọ náà àti Ààfáà tó fẹ́ gbé e níyàwó lẹ́jọ́, ilé ẹjọ́ náà fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n tàpá sí òfin tó ń dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé ti ìpínlẹ̀ ọ̀hún (Òǹdó) gbé kalẹ̀ lọ́dún 2007.
Lẹ́yìn atótónu àwọn olùjẹ́jọ́, ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ ọ̀hún ní ìtùbí ìnùbí , ó sì kàn án nípá fún Alihaji Yusuf láti tọwọ́ bọ̀wé pé ohunkóhun kò ní ṣe ọmọdébìnrin náà, àti pé, kó takété síi.
Ní báyìí, Kọmíṣọ́nnà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti ìdàgbàsókè àwùjọ ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Titilola Adeyemi ti fa ọmọ náà lé àwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́
Comments
Post a Comment