Posts

Showing posts from July, 2020

Ilé Aṣòfin àgbà pàṣẹ ìdádúró ètò ìgbani sísẹ́ Ìjọba àpapọ̀

Image
Fẹ́mi Akínṣọlá Ó dà bí ẹni pé ojú ẹ̀kọ ò jọ mímu lásìkò tí a wà yìí láàrin ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà lórí ètò ìgbani sísẹ tí ìjọba àpapọ̀ ń gbèrò rẹ̀. Èyí náà ló bí bí Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà ti kéde pé ki ìjóba dá iṣẹ́ ológún náírà oṣoosù tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ gba àwọn ènìyàn sí lábẹ́ àjọ tó ń gbani síṣẹ́ (NDE) láti mú ìrọ̀rùn bá ará ìlú nítorí àrùn Kofi--19 tó gba ayé kan Sáájú àsìkò yìí ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lù gbígba ènìyàn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnléláàdọ́rin ènìyàn lábẹ́ ètò náà. Lábẹ́ ètò yìí ẹgbẹ̀rún kan ọmọ Nàìjíríà tí yóò gba ẹgbẹ̀run lọ́nà ogún Náírà lósoosù fún oṣù mẹ́ta àwọn ènìyàn yìí yóò wá láti ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó yẹ kí ètò náà bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù kẹwàá ọdún yìí. Sùgbọ́n èdè àìyedè tó wáye láàrin mínísítà fún ètò iṣẹ́ Festus Keyamo àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní àná ọjọ́ Ìṣẹ́gun jọ bí ẹni pé ó ti pagidínà ètò náà. Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà Ajibola Bashiru to kéde ìdádúró ètò náà l...

Ilé ẹjọ́ yẹ àga mọ́ Ọba Ìkirè nídìí

Image
Fẹ́mi Akínṣọlá Ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti yẹ àga mọ́ Ọba Olatunde Falabi tó jẹ́ Akirè ti ìlú Ìkirè nídìí. Ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Ọṣun ti yẹ aga mọ Ọba Olatunde Falabi tó jẹ Akire ti ìlú Ìkirè nídìí. Awuyewuye lórí ẹni tí ipò ọba náà kàn ni Ìkirè ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1993 nígbà tí Ọba Fàlàbí gorí ìtẹ́. Èyí tó mú kí ọ̀kan lára àwọn tó ń du ipò ọba ọ̀hún, Ọmọba Tajudeen Olarewaju, láti ìdílé Aketula pe ẹjọ́ lòdì sí ọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́ lásìkò náà . Wọ́n fa ẹjọ́ náà títí tó fi dé Ilé ẹjọ́ tó gajù ní Nàìjíríà lọ́dún 2014, tí ilé ẹjọ́ ọ̀hún sì ṣèdájọ́ pé kìí ṣe Fàlàbí ni oyè náà tọ́ sí, bíkòṣe Ọlárewájú. Lẹ́yìn ìdájọ́ náà tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gbìyànjú láti yọ Ọba Fàlàbí lórí ìtẹ́. Ní èyí tó mú kí òun àti àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ gba Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ lọ, pé ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ tó ga jù náà kò sọ pé kí òun kúrò lórí oyè. Fàlàbí sọ pé Gómìnà àná nìpínlẹ̀ náà, Rauf Aregbesola ló pe òun sí ìpàdé kan ní ìlú Òṣogbo lọ́dún 2014. Àti pé nínú ìpàdé yìí n...

Mó ń du ẹ̀mi ọmọ mi ni wọ́n bù mí ládàá látàrí-- ìyá ọmọ tí wọ́n sá

Image
Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀rọ̀ ìpànìyàn tó ń di lemọ́ lemọ́ ní agbègbè Akínyẹlé ti wá di èkuru ọ̀ràn, tó ṣe pé, wọn ò tíì jẹ̀ kan tán tí wọ́n fi ń gbọn wọ́ òmí-ìn sáwo, bí àwọn ọdaran afurasí apani ṣètùtù ọ̀la ṣe sọ Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Akínyẹlé di ibùjókóò wọn, láì bìkítà akitiyan ọlọ́pàá. Bí kò bá wa rí bẹ́ẹ̀ kín ló tún bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù míràn ti ó wáyé ní agbègbè Akínyẹlé nílù Ìbàdàn ní ìdájí ọjọ́ Àìkú. Lọ́tẹ̀ yìí, arábìnrin kan, Adeola Bamidele àti ọmọ rẹ̀ obìnrin, Dolapo, ni àwọn agbébọn kan kọlù nínú ilé wọn. Déédé aago kan òru ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé , táwọn afurasí ọ̀daràn náà sì gba ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ alágbèéká méjì . Bákan náà ni wọ́n sá tìyá-tọmọ lọ́gbẹ́ ní orí, tí àwọn méjéèjì sì wà nílé ìwòsàn fún ìtọ́jú. Nígbà tó ń sàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà se wáyé, arábìnrin Adeola, tíí se ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta ní àdá ní àwọn afurasí ọ̀hún fi ṣá òun lásìkò tí òun ń du ẹmi ọmọ òun lọ́wọ́ ìkọlù, tí òun sì bá ara oun ninu agbara ẹjẹ. Àmọ́ Dolapo, tíí se ẹni ọdún mẹ́tàlélógún kò leè...

Níbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun , jálá epo fò fẹ̀rẹ̀ sí 143.80

Image
Fẹ́mi Akínṣọlá Ó ṣeéṣe kí àwọn ọmọ Orílẹ̀ yìí ó mọ̀ ọ́n lára ò, papà á bí àjàkálẹ̀ àrùn ṣe ń àwùjọ fínra yìí tí ètò ọrọ̀ ajé sì ti dẹnu kọlẹ̀, léyìí tó mú kí àtijẹ àtimu ọpọ ìdílé o pakasọ. T'òun ti bẹ́ẹ̀ náà ní ìjọba àpapọ̀ ń kéde pé ẹ̀kúnwó epo bẹntírò láti ọgọ́rùn ún náírà lé ní náírà mọ́kànlélógún àbọ̀ (N121.50) sí náírà mẹ́tàlélógóje  lé ní ọgọ́rin kọ́bọ̀(N 143.80). Àjọ PPPRA tó ń ṣàmójútó owó epo rọ̀bì ló ṣe ìkéde náà nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́sàn Ọjọ́rú. Àjọ náà ni "lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò kíkún àti nǹkan ti ọjà epo bẹtiróò ń sọ lágbàyé nínú oṣù kẹfà, àwọn ṣe àmójútó ìyé tó to gbé epo jáde tí ẹnikẹ́ni kò sì ní pàdánù owó" "Nítorí náà, a rọ àwọn ilé epo láti máa ta jálá epò bẹtiróò ní ogóje náìrà sí náírà mẹ́tàlélógóje ó lé ọgọ́rin kọ́bọ̀, fún oṣù keje ọdún 2020." A rọ gbogbo àwọn ilé epo aládàáni kí wọ́n ta ọjà wọ́n ni gbèdéke iye tí PPPRA pè é. Ẹgbẹ́ àwọn aládàáni tó ń ta epo bẹtiró ní Nàìjíríà (IPMAN) ti sàlàyé pé, gbogbo ìlànà tí ìjọba...

COVID-19: WORSHIP CENTRES, SCHOOLS TO REOPEN IN EKITI

Image
…..TO BE ISSUED CERTIFICATE OF READINESS BEFORE OPENING .......FRONTLINE MEDICAL PERSONNEL GET N2.5 BILLION LIFE INSURANCE ......RESIDENTS WITHOUT FACE MASKS RISK ARREST AND PROSECUTION Subject to fulfilment of some laid down protocols, worship centres in Ekiti State may resume for services as from Friday, July 17th. This is in line with the agreement reached by the State Government with leaders of religious organisations in the State. Governor Kayode Fayemi who disclosed this on Tuesday in a state-wide broadcast on the next stage in the State’s COVID-19 Response, said arrangements are in top gear to ensure that pupils and students return to school from July 20, as recommended by stakeholders in the education sector. The two largest markets in Ado Ekiti, the Oja Oba and Oja Bisi, according to the Governor, will now be open to lock-up shops only, subject to compliance with protocols stressing that street trading, makeshift stalls, kiosks, and open display of wares in the sa...