Mó ń du ẹ̀mi ọmọ mi ni wọ́n bù mí ládàá látàrí-- ìyá ọmọ tí wọ́n sá



Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ ìpànìyàn tó ń di lemọ́ lemọ́ ní agbègbè Akínyẹlé ti wá di èkuru ọ̀ràn, tó ṣe pé, wọn ò tíì jẹ̀ kan tán tí wọ́n fi ń gbọn wọ́ òmí-ìn sáwo, bí àwọn ọdaran afurasí apani ṣètùtù ọ̀la ṣe sọ Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Akínyẹlé di ibùjókóò wọn, láì bìkítà akitiyan ọlọ́pàá.

Bí kò bá wa rí bẹ́ẹ̀ kín ló tún bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù míràn ti ó wáyé ní agbègbè Akínyẹlé nílù Ìbàdàn ní ìdájí ọjọ́ Àìkú.

Lọ́tẹ̀ yìí, arábìnrin kan, Adeola Bamidele àti ọmọ rẹ̀ obìnrin, Dolapo, ni àwọn agbébọn kan kọlù nínú ilé wọn.

Déédé aago kan òru ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé , táwọn afurasí ọ̀daràn náà sì gba ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ alágbèéká méjì .

Bákan náà ni wọ́n sá tìyá-tọmọ lọ́gbẹ́ ní orí, tí àwọn méjéèjì sì wà nílé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Nígbà tó ń sàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà se wáyé, arábìnrin Adeola, tíí se ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta ní àdá ní àwọn afurasí ọ̀hún fi ṣá òun lásìkò tí òun ń du ẹmi ọmọ òun lọ́wọ́ ìkọlù, tí òun sì bá ara oun ninu agbara ẹjẹ.

Àmọ́ Dolapo, tíí se ẹni ọdún mẹ́tàlélógún kò leè sọ̀rọ̀ rárá nítorí oró ọgbẹ́ àdá tí wọ́n sá a, èyí tó jìn wọnú.

Nígbà tó ń fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún akọròyìn, òṣìṣẹ́ alárinà fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olugbenga Fadeyi sàlàyé pé lóòótọ́ ni ìkọlù ọ̀hún wáyé.

Fádèyí ní ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí kan lórí àwọn ìwà ìṣekúpani àti ìkọlù tó ń wáyé lágbègbè Akínyẹlé náà.

Bákan náà ló fi kún un pé wọn yóó se àfihàn àwọn afurasí tó wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ Akínyẹlé náà ní olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní Ẹlẹyẹle nílù Ìbàdàn.

A ó rántí pé ó ti tó obìnrin mẹ́rin àti ọkùnrin kan, Mujeeb Tirimisiyu, Barakat Bello, Grace Oshiagwu, Azeezat Shomuyiwa àti Olusayo Fagbemi, tí wọ́n ti pa ní agbègbè Akínyẹlé .

Comments