Ilé ẹjọ́ yẹ àga mọ́ Ọba Ìkirè nídìí


Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti yẹ àga mọ́ Ọba Olatunde Falabi tó jẹ́ Akirè ti ìlú Ìkirè nídìí.

Ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Ọṣun ti yẹ aga mọ Ọba Olatunde Falabi tó jẹ Akire ti ìlú Ìkirè nídìí.

Awuyewuye lórí ẹni tí ipò ọba náà kàn ni Ìkirè ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1993 nígbà tí Ọba Fàlàbí gorí ìtẹ́.

Èyí tó mú kí ọ̀kan lára àwọn tó ń du ipò ọba ọ̀hún, Ọmọba Tajudeen Olarewaju, láti ìdílé Aketula pe ẹjọ́ lòdì sí ọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́ lásìkò náà .

Wọ́n fa ẹjọ́ náà títí tó fi dé Ilé ẹjọ́ tó gajù ní Nàìjíríà lọ́dún 2014, tí ilé ẹjọ́ ọ̀hún sì ṣèdájọ́ pé kìí ṣe Fàlàbí ni oyè náà tọ́ sí, bíkòṣe Ọlárewájú.

Lẹ́yìn ìdájọ́ náà tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gbìyànjú láti yọ Ọba Fàlàbí lórí ìtẹ́.

Ní èyí tó mú kí òun àti àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ gba Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ lọ, pé ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ tó ga jù náà kò sọ pé kí òun kúrò lórí oyè.

Fàlàbí sọ pé Gómìnà àná nìpínlẹ̀ náà, Rauf Aregbesola ló pe òun sí ìpàdé kan ní ìlú Òṣogbo lọ́dún 2014.

Àti pé nínú ìpàdé yìí ni Aregbesola ti sọ fún òun níwájú Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ ọ̀hún àti Kọmíṣọ́nnà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ lọ́balọ́ba pé wọ́n ti yọ òun lórí ìtẹ́.

Nígbà tó ń ṣèdájọ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà, Adájọ́ A. B. AbdulKareem sọ pé Ọba Fàlàbí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti wà lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ìlú Ìkirè.

Adájọ́ ọ̀hún tẹ̀síwájú pé Ọmọba Tajudeen Olárewájú ni oyè ̣Ọba náà tọ́ sí.

Lẹ́yìn náà ló ní kó lọ rọọ́kún nílé, kí ẹni tí oyè ọ̀hún tọ́ sí le è bọ́ s'órí ìtẹ́.

Comments