Ilé Aṣòfin àgbà pàṣẹ ìdádúró ètò ìgbani sísẹ́ Ìjọba àpapọ̀


Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó dà bí ẹni pé ojú ẹ̀kọ ò jọ mímu lásìkò tí a wà yìí láàrin ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà lórí ètò ìgbani sísẹ tí ìjọba àpapọ̀ ń gbèrò rẹ̀. Èyí náà ló bí bí Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà ti kéde pé ki ìjóba dá iṣẹ́ ológún náírà oṣoosù tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ gba àwọn ènìyàn sí lábẹ́ àjọ tó ń gbani síṣẹ́ (NDE) láti mú ìrọ̀rùn bá ará ìlú nítorí àrùn Kofi--19 tó gba ayé kan

Sáájú àsìkò yìí ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lù gbígba ènìyàn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnléláàdọ́rin ènìyàn lábẹ́ ètò náà.

Lábẹ́ ètò yìí ẹgbẹ̀rún kan ọmọ Nàìjíríà tí yóò gba ẹgbẹ̀run lọ́nà ogún Náírà lósoosù fún oṣù mẹ́ta àwọn ènìyàn yìí yóò wá láti ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó yẹ kí ètò náà bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù kẹwàá ọdún yìí.

Sùgbọ́n èdè àìyedè tó wáye láàrin mínísítà fún ètò iṣẹ́ Festus Keyamo àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní àná ọjọ́ Ìṣẹ́gun jọ bí ẹni pé ó ti pagidínà ètò náà.

Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà Ajibola Bashiru to kéde ìdádúró ètò náà lásìkò to n bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Abuja, ó sọ pé ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà pé Festus Keyamo láti yọjú sí ilé aṣòfin láti sàlàyé lóri ọ̀nà ti wọ́n fẹ́ gbà láti gba àwọn ènìyàn sísẹ́ lábẹ́ ètò náà.

Ó ní "bí ǹkan ṣe ń lọ yìí mímú ètò náà wá sí ìmúṣẹ yóò mọ́wọ́ró díẹ̀ títí di ìgbà ti mínísítà bá le sàlàyé ara rẹ̀ lẹ́kunrẹ́rẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà.

Comments