Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàrin ọlọ́kadà àti òṣìṣẹ́ ọgbà àtúntò ní Ibadan
Fẹ́mi Akínṣọlá
Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ti ń pàkan ní òmí-ìn ń rú tú .
Ẹni ọ̀ràn ò ṣojú rẹ̀ rí, ẹ pé ó wá wí, ọ̀rọ̀ di bóò lọ kí o yà fún mi lọ́wùrọ́ọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní agbègbè gate nílùú Ìbàdàn níbi tí rògbòdìyàn ti bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọlọ́kadà àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà àtúntò tó ń bẹ ní Agodi.
Ohun tí ó ṣojú mi kòró sọ ni pé ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà àtúntò náà ló ṣekúpa ọlọ́kadà kan tí òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà sì fi ara pa ní agbègbè tí wàhálà náà ti ṣẹlẹ̀ .
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn awakọ̀ àti àwọn èèyàn tó ń fi ẹsẹ̀ rìn ló rọ́rí padà sí ibi tí wọ́n ti ń bọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ náà di wọ́lùkọlù.
Níbáyìí àwọn òṣìṣẹ́ ọlọ́pàá àti iléeṣẹ́ ológun ti dúró wámúwámú sí gbogbo agbègbè náà títí tí ó fi dé agbègbè Total Garden.
Lásìkò tó ń fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀, alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́,
Gbenga Fadeyi ṣe àlàyé pé lóòótọ́ ni fànfà wáyé ní agbègbè náà, "ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá àti ẹ̀ṣọ́ ààbò míì ti yọjú síbẹ̀ láti le mú kí àlàáfíà j'ọba".
Fadeyi fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọlọ́pàá kò yìnbọn fún ẹnikẹ́ni níbẹ̀ tako ìròyìn tó gba orí ayélujára kan wí pé ọlọ́pàá yìnbọn níbẹ̀.
Comments
Post a Comment