Olùdíje Dupò Ààrẹ Nàìjíríà rí, Wòlíì Ọlápàdé Àgòrò jáde láyé

 



Fẹ́mi Akínṣọlá


Àwáyé è kú kan kò sí, ó pẹ́, ó yá, kóówá ó padà sọdọ Elédùwà jínyìn bó ṣe gbókè èèpẹ̀ . Ìpapòdà èèyàn ló ń ṣàfihàn pé onítọ̀ùn ti dé wáàsinmi .

 Ikú tí pajú gbajúgbajà olóṣèlú tó tún jẹ́ Wòlíì, Ọ̀mọ̀wé Ọlápàdé Àgòrò dé o, baba ti dágbére fáyé pé ó dìgbà kan ná.


Ẹbí olóògbé náà ló fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́ ni ikú wọlé mú Wòlíì náà tó díje dupò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú National Action Council (NAC).

Lóru mọ́jú òní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kínní, oṣù Kọkànlá, ọdún 2020 ni Wòlíì náà jẹ́ hòo sí ìpè Olódùmarè.


Alhaja Adeola Àgòrò JP tó jẹ́ ọmọ olóògbé náà fi sójú òpó abánidọ́rẹ̀ẹ́ facebook rẹ̀ pé ikú ti wọlé mú ẹni rere náà lọ.

Wòlíì Ọlápàdé Àgòrò jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin kí ọlọ́jọ́ tó mú u lọ.


Ṣaájú ikú rẹ̀ ló ti ń ṣọ̀rọ̀ rere nípa ìyànsípò Aṣíwájú Bola Tinubu gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ lábẹ́ APC ní 2023.

Òun náà ni olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú NAC.


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ni àwọn ọmọ olóòkù fi s'órí ayélujára tí wọ́n sì fi ń dárò ẹni wọn tó lọ.

Comments