Seyi Makinde ṣàbẹ̀wò sí agbègbè tí ìró ìbọn ti ń dún n'Ìbàdàn

 



Fẹ́mi Akínṣọlá


Ṣé onílùú kò ní fẹ́ kó tú. Bẹ́ẹ̀ àwọn àgbà ní ń tí a kò bá fẹ́ kó bàjẹ́, ó ní bí a tií ṣe é. Gómìnà Ṣèyí Mákindé ti yọjú sí Iwo Road lóríi rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.


Láti Òwúrọ̀ ni ariwo ìbọn ti ń dún ní kíkan kíkan ní agbègbè Iwo road lọ sí Àbáyọ̀mí-Idi-Apẹ.


Ìròyìn tí a gbọ́ ni pé, àwọn jàǹdùkú kan fẹ́ yawọ àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Testing Ground ní òpópónà Iwo road, lẹ́yìn tí wọ́n dáná sun ọkọ̀ Operation Burst kan ní agbègbè náà.


Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń yin ìbọn, ni wọ́n ń fín tajútajú náà pẹ̀lú.


Ó ṣojú mi kòró ní àwọn ọlọ́pàá méjì ni àwọn jàǹdùkú náà pa, tí wọ́n sì dáná sun wọ́n.


Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùgbé àdúgbò náà ló ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn báyìí.

Comments