EndSARS: Mákindé sèlérí àtìlẹ́yìn fáwọn tó lùgbàdì ikú Òjijì

 



Fẹ́mi Akínṣọlá


Ṣé wọ́n ní ọmọ onílùú tòótọ kìí fẹ́ kó tú. Ìlú tá ò bá sì fẹ́ kó tú, a kìí faláboyún bẹ̀ ẹ́ ṣètùtù. Èyí ló mú kí Gómìnà Ṣèyí Mákindé,Lójú òpó abẹ́yefò Twitter , jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun ti ṣe àbẹ̀wò sí ìdílé mẹ́ta tí àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta ti ṣalábàápàdé ikú òjijì nítorí ìwọ́de EndSARS.


"A bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ yìí nípa ṣíṣe kóríyá fún àwọn ìdílé náà fún àdánù wọn, a sì tún sèlérí láti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún wọn".


"A bá gbogbo àwọn tó pàdánù èèyàn lásìkò ìwọ́de EndSARS kẹ́dùn. Gẹ́gẹ́ bí ìjọba, a kò níí sáré gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ díẹ̀ ṣẹ́yìn yìí, tó já sí ikú Isiaka Jimoh, Ganiyu Moshood àti Adeoye Taiwo.


Bákan náà, Gómìnà fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé òun ti ṣe àbẹwo sí ààfin Sọ̀ún ti Ògbómọ̀ṣọ́ tó sì ní òun ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fún Kábíyèysí ní Ọgọ́rùn mílíọ̀nù náírà láti bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe gbogbo nǹkan tó bàjẹ́ lásìkò tí àwọn olùfẹ̀hónúhàn yabo ààfin.

Comments

Popular posts from this blog

Sunday Musings: That Osun/Adeleke/Oyetola Court Judgment - By Bolaji Aluko

Crisis in Ekiti PDP Ahead Of 2022 As Fayose Group Splits over Anti Eleka Governorship Comment