EndSARS: Ẹ̀yin ọ̀dọ́ padà á lé, ẹ tí ṣọ̀rọ̀ sókè tó-- Ààrẹ̀ Buhari

 


Fẹ́mi Akínṣọlá


Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní olójú kan kò ní yajú rẹ̀ sílẹ̀, kí tàlùbọ̀ ó kó wọ̀ọ́.Látàrí bí gbogbo nǹkan ṣe di fọ́pomọ́yọ̀ ńlẹ̀ yìí ,Ààrẹ Buhari ti ké sí àwọn ọ̀dọ́ tó ń wọ́de káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti padà sílé olúkúlùkù wọn kí wọ́n sì dẹ́kun ìwà bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀dùn ọkàn wọn tí wọ́n fẹ́ kí Ìjọba gbọ́ tí dún korokoro létí òun àti Ìjọba òun.


Ààrẹ Buhari ti ní ìjọba òun kò ní fààyè gba ẹnikẹ́ni láti máa ba àwọn dúkìá ìlú jẹ́ àti pé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ń gbéná wojú ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni àti pé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóó fojú winá òfin Orílẹ̀ bó ṣe làá kalẹ̀ .


Ààrẹ Muhammadu Buhari bá àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ṣọ̀rọ̀ lórí wàhálà tó ti jẹyọ pẹ̀lú ìwọ́de #EndSARS tó gbòde lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.


Ààrẹ Buhari ní òun kò ṣàì mọ ìpèníjà aráàlú lórí ìwà kòtọ́ àwọn ọlọ́pàá ikọ̀ SARS náà.


Ó ní lóòótọ́ aráàlú lẹ́tọ̀ọ́ láti wọ́de kí wọ́n sì fi ẹ̀hónú wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin Nàìjíríà ṣe làá kalẹ̀,


Àmọ́ṣá òfin náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé kò sí aráàlú tí ìwé òfin fún láàyè láti fi èròńgbà fí fi ẹ̀hónú rẹ̀ hàn fi dí aráàlú míràn lọ́wọ́.


Ó ní gbogbo àwọn ẹ̀hónú márùn ún tí wọ́n fi kalẹ̀ ni Ìjọba òun tẹ́wọ́gbà tí òun sì ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ lórí rẹ̀.


Ààrẹ Buhari mẹ́nuba àwọn ìwà ìkọlù gbogbo táwọn olùwọ́de náà ti gbé ṣe eléyìí tó sì ní ó mú ìbànújẹ́ bá òun gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ, papàá jùlọ ikú àwọn èèyàn kan lásìkò náà.


Bákan náà ni Ààrẹ Buhari tún bu ẹnu àtẹ́ lu ohun tó pè ní Ìròyìn òfegè káàkiri àwọn Ìròyìn orí ayélujára gbogbo eléyìí tó ní ó ti kún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àwọ̀ tí kò tọ láwùjọ àgbáyé.


Ó ní irọ́ ni pé Ìjọba òun kò ní ìtara nípa ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nítorí pé onírúurú ìgbésẹ̀ àti ètò ni òun ti gbé kalẹ̀ láti ríi pé ayé dẹrùn fún aráàlú.


Ààrẹ Buhari fi kún un pé Ìjọba òun ti darí Àjọ tó ń rí sí ètò owó oṣù fáwọn òṣìṣẹ́ ọba lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti tètè ṣe iṣẹ́ lórí àfikún owó oṣù àwọn ọlọ́pàá tó àtàwọn òṣìṣẹ́ àjọ aláàbò yókù l'órílẹ̀èdè Nàìjíríà kí ó leè kún ojú ìwọ̀n.


Ààrẹ ní kí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé máa gbọ́ ọ̀rọ̀ lágbọ̀ọ́yé kí wọ́n tó máa gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ nípa orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Comments