Aráàlú gbé ajílẹ̀ àti oògùn apakòkòrò dípò oúnjẹ ìrànwọ́ Kofi-19 l'Ékìtì

 


Fẹ́mi Akínṣọlá


Ohun tí ìṣẹ́ òhun òsì pẹ̀lú àìmọ̀kan ń dáá sílẹ̀ láwùjọ kò kéré rárá. Ṣé òótọ́ ọ̀rọ̀ dé lẹ , èèyàn tí ebi ń pa kò ríran gaara, bẹ́ẹ̀ sì ni irúfẹ́ onítọ̀ùn kò gbọ́ fífi ìfé pè.


Lẹ́yìn ìkọlù tó wáyé níbi ìwọ́de EndSARS ní Lekki Toll Gate l'Eko, ní ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú kan bẹ̀rẹ̀ sí ní kọlu àwọn Ilé ti Ìjọba, kó àwọn oúnjẹ tó yẹ kó pín lásìkò ìgbélé Kofi-19 sí.


Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fídíò tó ń tàn kálẹ̀ lórí ayélujára, ìlú Èkó ni àwọn èèyàn náà ti kọ́kọ́ kọlu àwọn Ilé tí wọ́n kó oúnjẹ náà sí, tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ oúnjẹ kó.


Kò pẹ́ sí àsìkò náà tí àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ míràn bíi Ọ̀yọ́, Ọ̀ṣun, Kwara àti Èkìtì náà bẹ̀rẹ̀ sí ní-ìn kọlu irúfẹ́ ibùdó ìkó nǹkan pamọ́ sí bẹ́ẹ̀ ní ìpínlẹ̀ kóówá wọn, láti kó oúnjẹ ọ̀hún.


Ṣùgbọ́n ní ti ìpínlẹ̀ Èkìtì, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tí a gbọ́ ni pé, òògùn apakòkòrò àti ajílẹ̀ ni àwọn èèyàn jí kó dípò oúnjẹ.


Lára àwọn tó ké gbàjarè ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Babajide lórí ìkànnì abẹ́yẹfò Twitter tó sọ pé "gbogbo ìpínlẹ̀ ni àwọn èèyàn ti ń jí oúnjẹ ìrànwọ́ Kofi-19 tí Ìjọba fi pamọ́ kó, àyàfi Èkìtì tí àwọn èèyàn rẹ̀ ń kó òògùn apakòkòrò àti ajílẹ̀."


Yàtọ̀ sí Ọ̀gbẹ́ni yìí, àwọn èèyàn míràn náà tún ń lọgun lórí ayélujára pé májèlé ni ẹnikẹ́ni tó bá rò pé òun kó oúnjẹ Kofi-19 l'Ékìtì kó.

Ṣaájú ni Ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti kọ́kọ́ ké gbàjarè pé àwọn jàǹdùkú kan ń gbìmọ̀pọ̀ láti kọlu àwọn Ilé ìkẹ́rù sí ní ìpínlẹ̀ náà nítorí pé wọ́n ń wá oúnjẹ ìrànwọ́ Kofi-19.


Nínú àtẹjáde tí Kọmíṣọ́nnà fún ètò ìròyìn, Akin Omole fi léde, ó ní Ìjọba Èkìtì kò kó oúnjẹ ìrànwọ́ Kofi-19 pamọ́ síbìkan kan nítorí ó ti pín gbogbo rẹ̀ lásìkò ìgbélé.


Ṣùgbọ́n ṣé òótọ́ ni pé oúnjẹ ìrànwọ́ Kofi-19 ni àwọn èèyàn kó l'Ékìtì tàbí kò rí bẹ́ẹ̀?


Ìjọba Èkìtì kò tíì sọ ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ yìí.

Comments