Amẹ́ríkà tako ìyànsípò Okonjo-Iweala gẹ́gẹ́ bi olórí Àjọ WTO


Fẹ́mi Akínṣọlá


Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ọ̀tá ẹni kìí pòdù ọ̀yà bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ ṣe fẹ́ ẹ́ dà báyìí pẹ̀lú ìhà tí ilẹ̀ Amẹ́ríkà kọ sí orúkọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ngozi Okonjo-Iweala tí wọ́n fà sílẹ̀ láti di Olùdarí Àgbà fún àjọ okoowo l'agbaye, World Trade Organisation (WTO).


Ṣùgbọ́n, ọjọ́ kẹsàn -ún, oṣù Kọkànlá, ni ìrètí wà pé Àjọ náà yóó kéde èròńgbà rẹ̀.


Ọ̀pọ̀ nínú àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè nínú àjọ náà, tó darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ láti yan Ọ̀gá Àgbà tuntun, ló fọwọ́sí ìyànsípò Okonjo-Iweala.


Orílẹ̀-èdè America nìkan ni aṣojú tí kò faramọ́ ìyànsípò rẹ̀ níbi ìpàdé tó wáyé l'ọ́jọ́rú.


Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí a gbọ́, olùdíje fún ipò náà láti orílẹ̀-èdè South Korea, ni America faramọ́, nítorí "ìrírí tó ní nípa okoòwò, àti ipa láti ṣe amójútó dáadáa".

Wọn kò sọ ìdí tí wọ́n fi tako Okonjo-Iweala.


Ṣùgbọ́n, ó di ìgbà tí ìgbésẹ̀ tó kẹhin bá wáyé, kí ìjíròrò tó ó tán.


Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ń lọ, lóòótọ́ ni Okonjo-Iweala, ní ìbò tó pọ̀jù, àmọ́ ìyànsípò rẹ̀ kò tí ì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.


Ìjíròrò ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí bóyá Àjọ WTO faramọ́ ẹni tó ní ìbò tó pọ̀jù lọ.


Ìṣoro mìíràn ni pé orílẹ̀-èdè America kò faramọ́ Okonjo-Iweala".


"Nǹkan tí orílẹ̀-èdè America sì lè ṣe láti gbé èròńgbà wọn lẹ́yìn, ni láti wá àwọn orílẹ̀-èdè míì tí yóó darapọ̀ mọ́ wọn láti takòó ."


Ajọ̀ WTO ló má ń mójútó ìjíròrò àti àdéhùn okoòwò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè


Níbẹ̀ sì ni àwọn orílẹ̀-èdè ti le yanjú aáwọ̀ tó bá wáyé láàrin wọn nítorí okoòwò.


Okonjo, tó ti fi ìgbà kan jẹ́ Mínísítà fún ètò ìnáwó ní Nàìjíríà, ni obìnrin àkọ́kọ́ tó dé ipò náà láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí wọn ti dá Àjọ WTO sílẹ̀.

Comments