Ọmọ Ìpínlẹ̀ Edo, ẹ má dìbò fún Obaseki -- Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá


"Godwin Obaseki kò bá wa kópa nínú ìgbìyànjú láti fi òṣèlú àwarawa rinlẹ̀, nítorí náà kò yẹ lẹ́ni táá dìbò fún".


Aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú "All Progressives Congress,APC", Bola Ahmed Tinubu ló sọ ọ̀rọ̀ yìí saájú ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Edo.


Nínú fọ́nrán fídíò nǹkan bí Ìṣẹ́jú mẹ́rin náà, Tinubu ṣàlàyé ìdí tí òun ṣe fẹ́ kí àwọn ará ìpínlẹ̀ Edo má ṣe dìbò fún un.


Tinubu mú oríṣìríìṣí àkàwé ọ̀nà tí Obaseki kò fi ṣe ìṣe ẹni tó nífẹ̀ẹ́ òṣèlú àwarawa, tó sì ní èyí tó láti má ṣe dìbò fún Obaseki.


''Gbogbo àwọn àgbààgbà ilẹ̀ yìí pàrọwà sí i láti bọ̀wọ̀ fún òfin ilẹ̀ wa ṣùgbọ́n ó ketí ikún sí wọn''


Ó tẹ̀síwájú pé bẹ́ẹ̀ ló bẹ́gi dínà àwọn aṣòfinlé Edo láti jókòó ìjíròrò ní ilé aṣòfin.


''Ẹ má ṣe dìbò fún Obaseki, mo pàrọwà sí i yín''


Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni Godwin Obaseki ti díje dupò wọlé gẹ́gẹ́ bí i Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo.

Ìjà ló dé, orin dòwe tó wáyé láàrin òun àti Alága ẹgbẹ́, Adams Oshiomole ló ṣokùnfà bí Obaseki ti ṣe kúrò ní ẹgbẹ́ APC lọ sí PDP.


Nínú ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Edo tó ń bọ̀ lọ́nà, Obaseki àti Pásítọ̀ Ize Iyamu ni wọn yóó jọ du ipò.


Fọ́nrán fídíò Tinubu yìí jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ níbi tí Tinubu yóó ti jáde síta láti pàrọwà sí ará ìlú láti má ṣe dìbò fún ẹni tó kúrò nínú ẹgbẹ́ APC.


Ṣaájú gbogbo ọ̀rọ̀ ti Tinubu ń sọ nípa Obaseki kò ju pé kó ṣọ ọ lójú òpó abẹ́yefò Twitter tàbí nínú àtẹ̀jáde.

Comments