Àwọn ológun Mú Ààrẹ Boubacar Keita ti ilẹ̀ Mali si
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìlú tí rògbòdìyàn bá tí ń ṣẹlẹ̀, kìí fara rọ, torí pé omi àlàáfíà ibẹ̀ kìí tòrò fún ìlú láti pọn mu.
Ìró gbùdù wàhálà nílẹ̀ Mali ti forí sọbìkan báyìí, bí àwọn ológun ti mú Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Mali ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìdìtẹ̀ mọ́ Ìjọba ní ibùdó ológun Kati Camp.
Ààrẹ Ibrahim Boubacar Keita wà ní ilé rẹ̀ ní agbègbè Sebenikoro, Bamko nígbà tí àwọn ikọ̀ ológun an dé láti wá mú u ní nǹkan bí agogo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́.
Agbẹnusọ fún Ìjọba orílẹ̀-èdè Mali, Yaya Sangaré ṣàlàyé fún akọròyìn pé Ààrẹ Keita, Ọlóòtú Ìjọba orílẹ̀-èdè náà, Boubou Cissé, ọmọ rẹ̀, àti ìgbákejì rẹ̀ ni wọ́n mú.
Ó ti tó bíi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn báyìí tí orílẹ̀-èdè náà tí ń gbóná jọinjọin nítorí ọ̀rọ̀ òṣèlú níbẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ń ṣe ìwọ́de lórí pé kí Ààrẹ náà fi ipò sílẹ̀ nítorí ọ̀kan ò jọ̀kan ìkọlù àwọn agbésùnmọ̀mí ẹ̀sìn àti ìwà ìjẹkújẹ tó ń wáyé.
Ohun tó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ́de àwọn ọmọ ogún ló ṣe kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ di ìdìtẹ̀gbàjọba.
Comments
Post a Comment