Fẹ́mi Akínṣọlá Bí babaláwo bá tí ń kígbe ẹ̀fọ́rí, kí aláìsàn ó má nírètí mọ́. Ṣé kò wa sapá kan jànmọ́ pé ọ̀daràn tí wọ́n tí ṣàfíhàn rẹ̀ , Sunday Shodipe, afurasí tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ lórí àwọn ìṣekúpani tó wáyé lágbègbè Akínyẹlé ní ìlú Ìbàdàn ti pòórá bíi isó. Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kéde pé, arákùnrin náà ti sá lọ kúrò ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá níbẹ̀. Nínú àtẹjáde kan tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi síta látọ̀dọ̀ alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà, ni èyí ti jẹyọ. Àtẹjáde náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé, Sunday Shodipẹ ni afurasí tí wọ́n mú fún ìpànìyàn ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé tó wáyé lágbègbè Akínyẹlé tí wọ́n ṣe àfihàn rẹ̀ pẹ̀lú àwọn méjì míràn lọ́jọ́ kẹtàdínlógún, oṣù keje ọdún 2020, tí wọ́n sì gbe lọ sí iléẹjọ́, kí wọ́n tó dá a padà sí àhámọ́ ọlọ́pàá. Àmọ́ṣá, ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kọkànlá oṣù kẹjọ ni afurasí náà sá lọ kúrò nínú àhámọ́ ọlọ́pàá, tí àwọn ọlọ́pàá sì ní àwọn ṣì ń wá a. Bí ẹ kò bá gbàgbé, ikú Wasilat Adeola, Barakat Bello, Grace Oshiagwu, Mojeed Tirimisiyu tó jẹ́ ọmọ ọdú...