ìsìnkú Gómìnà Abíọ́lá Ajímọ̀bi
Báyìí ni gbogbo agbègbè Olúyòlé nílé olóògbé náà kún níbi ìsìnkú Gómìnà Abíọ́lá Ajímọ̀bi fún àwọn olùkẹ́dùn.
Kò ju èèyàn ogún péré tí wọ́n jẹ́ kó wà ní ibi ìsìnkú náà, ní ṣe làwọn ènìyàn dúró síta.
Déédé agogo méjìlá ọ̀sán ni wọ́n ṣe àdúrà ìdágbére fún un ní Mọ́sálásí. Sẹ́nétọ̀. Ishaq Abíọ́lá Ajímọ̀bi tó wà ní Òkè Àdó, Ìbàdàn.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano tí ó tún jẹ́ àna olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi, Abdullahi Umar Ganduje àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Jigawa, Mohammed Badaru Abubakar ti dé sí Mọ́sálásí Abíọ́lá Ajímọ̀bi tó wà ní Òkè -Àdó nílùú Ìbàdàn, níbi tí ètò àdúrà ti ń wáyé fún olóògbé.
Wọ́n gbé òkú Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi bọ́ọ́lẹ̀ nínú ọgbà Ilé rẹ̀ ní Olúyòlé, Ìbàdàn.

Comments
Post a Comment