ASUU, ìjọba ìpínlẹ̀, ìjọba àpapọ̀ forígbárí lórí ìwọlé Fásitì

 



Femi Akinsola 


Àwọ́n aláṣẹ Ìjọba àpapọ̀ ti fi ìmọ̀ràn síta gẹ́gẹ́ bí àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe ti kéde ọjọ́ tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ yóó wọlé.


Ìpínlẹ̀ Èkó àti Ọ̀ṣun ní ìhà Gúúsù -ìwọ̀ Oòrùn ti ní àwọn  ilé ẹ̀kọ́ yóó di ṣíṣí lọ́jọ́ Kẹrìnlá àti Ìkọkànlélógún oṣù kẹsàn án ọdún 2020.


Ìjọba àpapọ̀ gan an  ti wá fi ìpè síta látàrí bí àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ ṣe níí lérò yìí pé, kí wọ́n ṣọ́ra lórí bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́ torí pé ewu sì wà lóko lóńgẹ́.


Boss Mustapha tó jẹ́ akọ̀wé ìjọba àpapọ̀, tó tún jẹ́ Alága ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ Kofi-19 fi ìkìlọ̀ yìí léde lọ́jọ́ Ajé ní ìlú Àbújá níbi ìpàdé ìkejìlélọ́gọ́ta Ìgbìmọ̀ náà.


Ó ní bí orílẹ̀-èdè ṣe ń pinu láti ṣí àwọn ibi ìpéjọpọ̀ ìtagbangba, wọ́n gbọdọ̀ ríi pé wọ́n ṣì ń ṣe ohun gbogbo láti borí . Mínísítà fún ètò ìlera ní agbára àìsàn Kofi-19 kò re 'bìkan, ó pé ó léwu tó sì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn.'Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ni Fásitì ní Nàìjíríà, ASUU ti kìlọ̀ fún àwọn Ìjọba ìpínlẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe ṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga lásìkò yìí.


Ẹgbẹ́ ASUU ń fẹ́ kí Ìjọba mú sùúrù títí di ìgbà tí wọ́n bá leè rí ọ̀nà gbòógì láti dínwọ́ àrànká àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì kù.


Ẹgbẹ́ náà ní bí nǹkan ṣe wà lásìkò yìí, ó fẹ́ẹ̀ ẹ́ má le è tíì sí ààyè fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga Ìjọba láti tẹ̀lé òfin ìjìnàsíraẹni.


Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn ọmọ Ilé ẹ̀kọ́ girama tó wà ní kíláàsì àṣekágbá nìkan ló ń lọ Ilé ẹ̀kọ́ káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì Nàìjíríà láti ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdún 2020 láti le kọ ìdánwò wọn bíi WAEC àti NECO. Ẹ̀wẹ̀, Mínísítà abẹ́lé fún ètò ẹ̀kọ́ , Họnọrébù Emeka Nwajiuba sọ pé Ìjọba àpapọ̀ kò tíì sọ ọjọ́ tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ yóó wọlé jákèjádò ṣùgbọ́n ọjọ́ èyí táwọn Ìjọba ìpínlẹ̀ kéde ń kọ àwọn òbí lóminú gidi gan.

Comments