Sẹ́nétọ̀ Ajímọ̀bi dágbére f'áyé lẹ́ni ààdorin ọdún !
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ikú pọdẹ tapótapó, ikú paláhéré, ikú pàgbẹ̀ tebè tebè, ikú pàkọ̀kọ́, omi àgbọn dànù. kìnhùn lọ níjù,kowéè ké , kò ha.Lọ́wọ́ lọ́wọ́, ìròyìn tí a gbọ́ ni wí pé, gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tó tún ti jẹ́ Sẹ́nétọ̀ tẹ́lẹ̀rí nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Nàìjíríà, Sẹ́nétọ̀ Isiaka Abíọ́lá Ajímọ̀bi ti dágbére f'áyé,a àgbà olóṣèlú wọ kàá ilẹ̀ sùn.
Ṣaájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ohun tá a mọ̀ ni wí pé ìròyìn ń tàn káàkiri pé ó ń sàìsàn nítorí pé ó ti lùgbàdi àjàkálẹ̀ àrùn Kofi-19 .
Àwọn ìròyìn míì tilẹ̀ sọ wí pé, àìsàn inú ọkàn ló ń dà á láàmú ,nígbà tí àwọn kan tún ní ìtọ ṣúgà ni.
Abíọ́lá Ajímọ̀bi ni Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàrin ọdún 2011 sí ọdún 2019, kó tó wá du ipò Sẹ́nétọ̀ láti ṣojú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nílé Aṣòfin àgbà lọ́dún 2019 ṣùgbọ́n kò wọlé.
Ṣaájú kó tó du ipò gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe sáà rẹ̀ tán lọ́dún 2019, ó ti ṣe Sẹ́nétọ̀ fún sáà kan láàrin ọdún 2004 sí 2007.
Ẹni àádọ́rin ọdún ni Sẹ́nétọ̀ Ajímọ̀bi kó tó jáde láyé.
Comments
Post a Comment