Oyè adelé Alága APC bọ́ lọ́wọ́ Ajímọ̀bi,Buhari fòǹtẹ̀ lu Giadom
Fẹ́mi Akínṣọlá
A kìí bẹ̀rù ikú,bẹ̀rù àrùn, ká ní kí ọmọ ẹni ó kú sinni. Bẹ́ẹ̀, sàn-án làá rìn, ajé ní-ìn múni pẹ́ kọrọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, gbogbo awuyewuye tó ń wáyé lórí ẹni tí yóó jẹ asáájú fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti dópin nírọ̀lẹ́ Ọjọ́rú .
Ìdí ni pé Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kéde pé ẹni tó yẹ nípò ìgbákejì Alága fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni ìgbákejì Alága ẹgbẹ́ tẹ́lẹ̀, Victor Giadom.
Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, iléẹjọ́ ló yọ Alága tẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomọlẹ, tí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá ẹgbẹ́ sì kéde pé Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi ni ipò náà tọ́ sí.
Láti ìgbà náà sì ni ara kò rọ okùn, tí kò sì rọ adìẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Àtẹjáde kan tí agbẹnusọ fún Ààrẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu fi síta lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀ lórúkọ Ààrẹ Orílẹ̀ yìí ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ náà.
Shehu ní Ààrẹ ti gba ìmọ̀ràn tó dájú nípa ohun tí òfin ilẹ̀ wa sọ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, tó sì fara mọ́ ọ pé ẹ̀yìn Victor Giadom ni òfin gbè sí.
"Bákan náà, nítorí pé Ààrẹ Buhari máa ń wà lẹ́yìn òfin, Ààrẹ yóó bá adelé Alága tuntun náà se ìpàdé lati ori ẹrọ ayelujara ní ọ̀sán ọ̀la."
Iléeṣẹ́ Ààrẹ wá rọ àwọn akọròyìn láti dẹ́kun dídá awuyewuye sílẹ̀, kí wọ́n má sì fààyè gba ṣíṣe ìtumọ̀ òfin lọ́nà òdì lórí ọ̀rọ̀ náà.
Comments
Post a Comment