Mí ò bẹ̀bẹ̀ f'òyè igbákejì alága APC - Abiola Ajimobi
Fẹ́mi Akínṣọlá
Yorùbá ní èèyàn tí ìfà kò bá tọ́ sí, níí pè é ní hàráámù bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye ló tí súyọ lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC kéde Abíọ́lá Ajímọ̀bi gẹ́gẹ́ bí igbákejì alága APC.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí, Abíọ́lá Ajímọ̀bi ti sọ pé àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú( All Progressives Congress, APC) gbàgbọ́ nínú òun ni wọ́n ṣe fi òun jẹ Igbákejì Alága ẹgbẹ́ náà.
Ajímọ̀bi ní kìí ṣe pé òun bẹ̀bẹ̀ fún ipò ọ̀hún, ṣùgbọ́n àwọn alákòóso APC rí òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣe é fọkàn tán ni wọ́n ṣe fi òun sí ipò náà ní ìhà gúúsù Nàìjíríà.
Nígbà tó ń f'èsì sí ọ̀rọ̀ tí àwọn alátakò rẹ̀ sọ lórí ipò tuntun náà, Ajímọ̀bi sọ pé ẹgbẹ́ APC mọ irú àtúnṣe rere tí òun leè mú bá ẹgbẹ́ náà ní gúúsù Nàìjíríà àti ní orílẹ̀-èdè-ede yìí lápapọ̀.
Ajímọ̀bi, nínú ọ̀rọ̀ tó fi síta látẹnu agbẹnusọ rẹ̀, Bolaji Tunji, sọ pé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò le gbàgbé ipa ribiribi tí òun kó lásìkò ìṣèjọba bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ó sọ pé nítorí náà, tí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ APC bá lérò pé òun ni ipò náà yẹ, kò sí alátakò tó le è yí i padà.
Ẹ̀wẹ̀, Adébáyọ̀ Shittu tó jẹ́ mínísítà àná fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ sọ pé ó le ṣòro fún ẹgbẹ́ APC láti rí ìbò kankan nínú ìdìbò ọdún 2023, tí ẹgbẹ́ náà kò bá yanjú ìṣòro abẹ́lé tó ní.
Comments
Post a Comment