INEC kọ lẹ́tà APC láti ṣe ìbò abẹ́nú l‘Ondo
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà ní bí eégún kò bá ṣe n tó tóbi, atọ́kùn rẹ̀ kìí tú ìdí rẹ̀ wò.
Àjọ olómìnira tó ń ṣe kòkárí ètò ìdíbò Orílẹ̀ yìí tí fọnmú báyìí pẹ̀lú gbólóhùn pé, a kìí fini joyè àwòdì, kí á má leè gbé adìẹ.
Èyí kò ṣé látàrí gàdàgùdù omi wàhálà tó ń rú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú( All Progressives Congress, APC)ṣe ń fi ojoojúmọ́ gbóná janjan ní ìpińlẹ̀ Edo, bákan náà ló jọ bí ẹni pé ẹgbẹ́ náà kò tún rójúùtú ètò ìdìbò abẹ́nú láti yàn olùdíje gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ náà nípìnlẹ̀ Òǹdó .
Lọ́sàn yìí ni àjọ tó rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà (INEC) fi àtẹjáde kan síta pé, ìwé ìfitóniléti tí ẹgbẹ́ APC nípìnlẹ̀ Òǹdó kọ sí olú ilé iṣẹ́ ẹgbẹ́ náà l'Abuja láti pe òun fún ìdìbò àbẹ́nu wọ́n, kò kójú òṣùwọ̀n tó nítorí pé adelé akọ̀wé àpapọ̀ ẹgbẹ́ APC ní Nàìjíríà nìkan ló buwọ́ lu lẹ́tà náà.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹjáde náà ṣe sọ, ìwé ìfitónilétí ti ó tẹ ilé ẹgbẹ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹfà ọdún yìí kò ni àbuwọ́lù àlága àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà nínú.
Àtẹjáde tí Rose Oriaran-Anthony, tó jẹ́ akọ̀wé àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà (INEC) buwọ́lù sàlàyé pé, ìdìbò abẹ́nú tó yẹ kó wáyé ní ogúnjọ́ oṣù kèje ọdún yìí, le má ṣeéṣe nítorí pé àlága àpapọ̀ ẹgbẹ́, àwọn akọ̀wé àpapọ̀ ẹgbẹ́, ló yẹ kí wọ́n jọ buwọ́lùú.
Comments
Post a Comment