Èèyàn 452 ló lùgbàdì àrùn Kofi- 19 nílẹ̀ yìí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC, ti kéde èèyàn 452 míràn tó ní àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì ní Nàìjíríà.
Èyí sì ti mú kí àpapọ̀ àwọn tó ti ràn ní Nàìjíríà ó pé 21,371 báyìí.
Àkójọpọ̀ iye àwọn tó ní-in nìyí:
Àrùn náà ti pa ènìyàn 533, àwọn 7,338 sì ti rí ìwòsàn.
Ènìyàn 675 ni èsì àyẹ̀wò sọ pé ó ní Covid-19 ní Nàìjíríà ní 24/06/2020
Àjọ NCDC kéde pé ènìyàn 675 ni èsì àyẹ̀wò tún fihàn pé ó ti ní Kofi-19 ní Nàìjíríà.
Ìpínlẹ̀ Èkó ní 288, Ọ̀yọ́ sì tẹ̀le pẹ̀lú 76.
Àwọn tó kù ni:Rivers-56
Delta-31, Ebonyi-30
Gombe-28, Ondo-20
Kaduna-20,Kwara-20
Ogun-17, FCT-16
Edo-13, Abia-10
Nasarawa-9, Imo-9
Bayelsa-8, Borno-8
Katsina-8 ,Sokoto-3
Bauchi-3, Plateau-2
Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó ti pé ènìyàn 20,919 tó ti ní àrùn náà.
Comments
Post a Comment