Àwọn Apànìyàn kò rí t'Ọ̀gá ọlọ́pàá Ọ̀yọ́ rò l'Akínyẹlé
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé bí ẹyin àgbà bọ̀ ẹ ní olè kò níí ja àgbà, kó má ṣe é lójú fìrí, bó o wá ni ti àdúgbò Akínyẹlé àti agbègbè rẹ̀ yìí ṣe wá jẹ́ tí àbíkú àwọn oníṣẹ ibi wọ̀nyí ń sọ olóòògùn àwọn ọlọ́pàá di èké. Pẹ̀lú gbogbo akitiyan tọ̀sán tòru, àwọn ajániláyà pàtì mẹ́mìín ẹni lọ o gbèrò àti dẹ́kun dídá ẹ̀mí àwọn èèyàn légbodò.
Ni báyìí, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tún ti múgbe bọnu pé, ní aago márùn-ún ìdájí ni wọ́n pa obìnrin kan, níwájú ilé rẹ̀.
Kàkà kéwé àgbọn dẹ̀ ní àdúgbò Akínyẹlé nílù Ìbàdàn tí wọ́n ti ń pa àwọn èèyàn lemọ́lemọ́ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ko ko ko ló ń le sí i.
Ìdí ni pé wọ́n tún ti pa obìnrin mìíràn ,Olusayo Fagbemi, ládùgbóò Akinyele náà yàtọ̀ sí Mujeed tí wọ́n pa níbẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, òṣìṣẹ́ alárinà fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olugbenga Fadeyi ní aago márùn-ún ìdájí Ọjọ́ru ni wọ́n pa obìnrin náà.
"Ní déédé aago mẹ́fà ku ogún ìṣẹ́jú ni ìdájí Ọjọ́rú ni wọ́n kọlu obìnrin kan, Olusayo Fagbemi, ẹni ọdún méjìlélógójì, lásìkò tó ń fọ abọ́ níwájú ilé rẹ̀, tó sì ní ọgbẹ́ lórí."
Fadeyi tẹ̀síwájú pé igbe rara obìnrin náà ló mú kí ọkọ rẹ̀ sáré jáde láti inú ilé, tó sì bá ìyàwó rẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀, tí àwọn èèyàn tó ṣiṣẹ́ láabi náà sì ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ.
Ó ní wọ́n gbé obìnrin náà lọ sílé ìwòsàn, àmọ́ ẹ̀pa kò bóró mọ́ nítorí obìnrin náà ti jáde láyé.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní, adìẹ ń làágùn ìyẹ́ ni ò jẹ́ á mọ̀. Ó ní aáyan tí ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn amòòkùnṣèkà, olubi ẹ̀dá náà.
A ó rántí pé, ó ti tó obìnrin mẹ́rin àti ọkùnrin kan, Mujeeb Tirimisiyu, Barakat Bello, Grace Oshiagwu, Azeezat Shomuyiwa àti Olusayo Fagbemi, tí wọ́n ti pa ní Akínyẹlé náà, tí àwọn ọlọ́pàá kò sì tí ì mọ àwọn èèyàn tó pa wọ́n.
Comments
Post a Comment