Ajímọ̀bi kò gbọdọ̀ kú, ẹ lọ wólẹ̀ àdúà--APC Ọ̀yọ́



Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹgbẹ́ òṣèlú( All Progressives Congress, APC) ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ẹgbẹ́ àwọn Alága Ìjọba ìbílẹ̀, ALGON, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti bẹ̀rẹ̀ ètò ààwẹ̀ àti àdúrà fún ìlera adelé Alága ẹgbẹ́ òsèlú APC nipinlẹ Oyo, Abíọ́lá Ajímọ̀bi.

Àtẹjáde kan tí ẹgbẹ́ APC fisíta nílù ú Ìbàdàn wá rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ wọn láti gba ààwẹ̀ àti àdúrà ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹfà ọdún 2020.

" A rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ APC láti gbàdúrà kíkan  kíkan fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí, Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi. A gbàdúrà kí ara rẹ̀ yá kíá kíá".

Nínú àtẹjáde míì tí Alága ẹgbẹ́ ALGON, ọmọba Ayodeji Abass Aleshinloye fọwọ́ sí, ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé  àjọgbà ni ààwẹ̀ àti àdúrà náà kò báà jẹ́ níta gbangba ṣùgbọ́n nítorí àkókò tí a wà yìí, èyí tí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì ń darí, ni wọ́n ṣe ní kí oníkálùkù gbà á ní àdágbà.

Ó ní "yálà ẹnikẹ́ni ro ikú tàbí ìyè rò ó, gbogbo èèyàn ló jẹ gbèsè ikú tí wọ́n sì  gbọdọ̀ san án, torí náà, kí ló dé táa fẹ́ kánjú túfọ̀ rẹ̀ nígbà tí àkókò rẹ̀ kò tíì tó. Èèwọ̀ ni, kò dá a, kí èèyàn má a ro ikú ro alààyè , tàbí ẹni táa rò sí ọ̀ta ẹni".

"Ọlọ́run ló ń fún ni, tó sì ń gbà á, fún ìdí èyí, kò sẹ́ni tó lágbára lórí ayé ẹlòmíì".

Abass ní ọlọ́yàyà èèyàn ni Sẹ́nétọ̀ Ajímọ̀bi, ó sì yẹ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà kọ etí ikún sí irú Ìròyìn bẹ́ẹ̀.

Bí ẹ ò bá gbàgbé, Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi tó wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn látàrí pé ó lùgbàdi Kofi-19, ni àwọn kan n tan iroyin kalẹ pe o ti ku.

Ẹgbẹ́ ALGON Ọ̀yọ́ ní "a fẹ́ fi yée yín pé, Sẹ́nétọ̀ wa Abíọ́lá Ajímọ̀bi, adarí wa kò kú, kò sí ní kú, bí kò ṣe yíyè".

Wọ́n ní "Ajímọ̀bi tí a mọ̀ sí ẹni tó kó Ọ̀yọ́ òde òní ṣe iṣẹ́ ribiribi, ó sì tún sin ìpínlẹ̀ rẹ̀ fún odidi ọdún mẹ́jọ, kò sì wá yẹ kí wọ́n ro ikú rò ó, papàá lásìkò yìí tí ó ti gba ìgbéga láti tukọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní gbogbo Nàìjíríà.

Comments