Sunday Igboho Ro Ajo ọlọ́pàá láti wá ìbejì Akeugbagold síta
Fẹ́mi Akínṣọlá
Èèkàn àwùjọ kan, Oloye Sunday Adeyemo, tí gbogbo èèyàn mọ si Sunday Igboho, ti sọ̀rọ̀ lórí ìbejì onímọ̀ kan nípa ẹṣin islam, Sheikh Taofeeq Akeugbagold, tí àwọn gende agbebọn gbé lọ lọ́jọ́ Satide. Igboho, lásìkò to ń takurọsọ pẹ̀lú àwọn akoroyin kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, rawọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn agbofinro nipinlẹ Oyo, láti ṣíṣẹ kára, fi doola ẹ̀mí àwọn ọmọdé méjèèjì náà lọ́wọ́ ewu.
Bákan náà ló tún rọ gbogbo àwọn agbófinró yíká orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, láti pawọ́ pọ̀ ṣe àwárí ìbejì ọ̀hún, kí wọ́n sì tún rí dájú pé àwọn olubi ẹ̀dá tó ṣiṣẹ́ láabi náà, fi imú kò ata òfin.Igboho ní ara Abiamọ tá òun nígbà tí òun gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tó sì tún bá òun lójijì, pẹ̀lú àfikún pé, ìwà ajọ́mọgbé náà kò bójú mu rárá. Ó wá ń para pòrò pé irú àwọn ìwà ọ̀daràn báyìí kò yẹ kó máa wáyé làwọn Ìpínlẹ̀ àti orílẹ̀ èdè tí ìjọba ti ń ná owó gọbọi lórí ìpèsè ètò ààbò àti mímú àdínkù bá àwọn ìwà ọ̀daràn lóníran ǹ ran.
Comments
Post a Comment