Ṣé lóòtọ ni àwọn agùnbánirọ̀ kò ní gba owó oṣù kẹrin àti ìkaàrún?
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní, ọ̀rọ̀ òkèèrè bí ò lé kan, a dín kan. Èyí ló mú kí ajọ àgùnbánirọ̀ lórìlẹ-èdè Nàìjíríà (NYCS) kéde pé àwọn yóò san owó oṣù Kẹrin àti ìkaàrún fún wọ́n láì mú ìwé tí wọ́n ń buwọ́lù lósoosù wá. láti fòpin sí wọ́n ní wọ́n pé , tí àwọn èèyàn kan ń gbé kiri.
Nínú àtẹ̀jáde kan ti adarí ìròyìn àjọ náà Adenike Adeyemi buwọ́lù ló ti sàlàyé pé wọn kò nílò láti buwọ́lu iwé kankan kí wọ́n tó gba owó ti osù kẹrin àti ìkaàrún ọdún 2020.
Ó ní àtẹjáde yìí wáyé nítori ìròyìn òfegè tó ń tàn ká pé adarí àjọ NYSC sọ pé owó oṣù kẹrin àti ìkaàrún kò ní tẹ àwọn àgùnbánirọ̀ lọ́wọ́ nítorí wọ́n yóò lòó láti gbógun ti àrùn apinni léèmí Covid 19.
Comments
Post a Comment