Ọ̀jọ̀gbọ́n Dibú Ọ̀jẹ́rìndé , Akọ̀wé Jánbù tẹ́lẹ̀ pàdánù ọ̀pọ̀ dúkìá sọ́wọ́ ICPC
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní iná kò mojú ẹni tó dáa, bẹ́ẹ̀ ni òfin ò mojú ẹni to gbé e kalẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí o, bí Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Àbújá tí pàṣẹ pé àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjé, ICPC, gbé ẹsẹ lé àwọn dúkìá kan tó jẹ́ ti akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fún àjọ JAMB, Ọ̀jọ̀gbọ́n Dibú Ọ̀jẹ́rìndé .
Lára àwọn dúkìá tí Ọ̀jẹ́rìndé pàdánù ṣọ́wọ́ àjọ ICPC ni iléeṣẹ́ Rédíò Gravity FM tó wà n'ilu Igboho, ilé ẹ̀kọ́ Sapati tó wà lójú ọ̀nà Ajasẹ Ipo, n'ílù ú Ilorin, ilé epo Soka tó wà n'ilu Ìbàdàn àti ilé ìtura Òkè Afin tó wà níwájú Fáṣítì ìmọ̀ ẹ̀rọ Ladoke Akintola n'ílù ú Ogbomoso.
Àwọn dúkìá yókù tí Ọ̀jẹ́rìndé yóó pàdánù ni, ilé epo àti gáàsì Doyin tó wà nílùú Ìbàdàn, ilé Tejumola tó wà ní Ikeja n'ílù ú Èkó tó fi mọ́ ilé àwòsífìlà kan tó wà lójúlé Kẹrìnlá, Yobe close, Maitama n'ílù ú Àbújá pẹ̀lú dúkìá rẹ̀ míràn tó wà ní orílẹ̀ èdè South Africa.
Kódà, Ọ̀jẹ́rìndé tún pàdánù àwọn ìpín Ìdókòwò àti owó tó níkìmí tó ní láwọn ilé ìfowópamọ́sí sí ọwọ́ àjọ ICPC.
Ìkéde nípa àwọn dúkìá yìí, tí Ójẹrinde pàdánù sì ọwọ́ àjọ ICPC ni ilé ẹjọ́ ti tẹ̀ síta, lójú àwọn ewé ìwé ìròyìn kan nílẹ̀ wa .
Adájọ́ Ijeoma Ojukwu, lásìkò tó ń gbé àṣẹ náà kalẹ̀ tún kéde pé, owó ìlú ni Ọ̀jẹ́rìndé fi kó àwọn dúkìá náà jọ, èyí tíì ṣe èrè tó rí láti ara ìwà àjẹbánu tó lòdì sofin.
Adájọ́ Ojukwu ṣàlàyé síwájú pé, ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ láti ra àwọn dúkìá náà gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ méjì péré nígbà tí ìjọba àpapọ̀ kò sì gbọ́dọ̀ jogún àwọn dúkìá náà lẹ́yìn ó rẹyìn.
Àjọ ICPC ni yóò sì máa ṣe àkóso àwọn dúkìá náà. Ọ̀gbẹ́ni David Igbodo, tíì ṣe igbá-kejì Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, ni wọ́n yàn bíi alákòóso fìdí hẹ ẹ́ lórí àwọn dúkìá náà, títí t'ílè ẹjọ́ yóò fi gbé àṣẹ míràn kalẹ̀ lórí àwọn dúkìá náà.
Comments
Post a Comment