Ní Kàdúná, òfin kónílé ó gbélé yóò tẹ̀síwájú fóṣù kan

By Fẹ́mi Akínṣọlá



Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní bí iná ò bá tán láṣọ, ó seése kí ẹjẹ wọ̀rù wọ̀rù ṣẹ́kù lórí èékánná. À ti pé, ogun tí yóó bá wọ lé kóni,  ọ̀nà la tií pàdé rẹ̀.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kàdúná ti kéde àfikún iye ọjọ́ kónílégbélé f’oṣù kàn sí i .

Gómìnà Nasir El-Rufai tó kéde ọ̀rọ̀ yìí ní ìgbésẹ náà jẹ́ ọnà àti dẹkùn àjàkálẹ̀ apinni léèmí "Covid 19" náà.

Lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ ló ti sàlàyé pé níse ni òun tẹ̀lé amọran tí ìgbìmọ̀ tó n gbógun ti àrùn náà, eléyìí tí igbákejì òun ń darí fi léde.

Ní báyìí àṣẹ yìí tí f'ẹṣẹ̀ múlẹ̀ láti ọjọ́ Àìkú tí ṣe ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin.

Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹta ní ìjọba tí ṣaájú fi Ìṣéde àkọ́kọ́ lé'lẹ̀ ni ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Àwọn ilé ẹjọ́ alágbèéká yóò wà níta láti dájọ́ fáwọn tó bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin yí .

Bẹ́ẹ̀ ni El Rufai ní àwọn yóò gbẹ́sẹ̀ lé ọkọ̀ tó bá rìn níta láì ní ìyọ̀ǹda ìjọba.

Comments