Fáyemí ṣàfikún òfin kónílé-ó-gbélé, ó korò ojú sí bí wọ́n se jí Kọmíṣọ́nnà rẹ àti àwọn kan gbé
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ọ̀mọ̀wé Káyọ̀dé Fáyẹmí ti ṣàfikún òfin kónílé-ó-gbélé nílù ú náà pẹ̀lú ọ̀sẹ̀ kan, bẹ́ẹ̀ ló bẹnu àtẹ́ lu bí wọ́n se jí Kọmíṣọ́nnà rẹ̀ fétò ọ̀gbìn Ọ̀gbẹ́ni Olabode Folorunso gbé.
Fáyẹmí ṣọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ lásìkò tó ń jábọ̀ fún àwọn ará ìlú lórí ibi tí nǹkan dé láti ìgbà tí òfin kónílé-ó-gbélé ti bẹ̀rẹ̀.
Fáyẹmí fi àìdùnnú rẹ̀ hàn bí wọ́n jí Kọmíṣọ́nnà fún ètò ọ̀gbìn,Olóyè Folorunsho Olabode àti àwọn mìíràn,léyìí tó mú ẹ̀mí olórí ìjọba ìbílẹ̀ ilejemeje .
Gómìnà fi dá wọn lójú pé ìgbésẹ̀ tó yẹ tí bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú náà,nígbà tó ń rọ àwọn elétò ààbò láti sapá wọn fáàbò ẹ̀mí àwọn èèyàn náà.
Ṣaájú ní ìròyìn tí ṣọ pé wọ́n tí jí Kọmíṣọ́nnà àti àwọn èèyàn méjì nílù ú náà gbé ṣá lọ sí ibi tí ẹnikẹ́ni ò mọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kọmíṣọ́nnà ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà Amba Asuquo ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni, àti pé òun ti da àwọn ikọ̀ òun síta fún àwárí wà láàyè àwọn èèyàn tí wọ́n jígbé náà.
"Mo mọ rírí ìfaradà yín fún bí i ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sẹ́yìn tí a ti ṣàgbékalẹ̀ òfin kónílé-ó-gbélé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kọ̀lọ̀rànsí kan o gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni abẹ òfin náà yóó siṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀ fúnwọn, kó lè jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn mìíràn.
Àjùmọ̀ gbá gbọ́ yé wa yìí ti sèso o re, mú àdínkù bá ìtànkalẹ̀ àrùn yìí,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pa ọrọ̀ ajé ìlú àti ti kóówá lára"
Gómìnà ní òfin tó dé ìrìnà ọkọ̀ láti ìlú kan sí ìlú kejì sì dúró digbí, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ sí àpéjọ ẹlẹ́sìn, olóṣèlú, ọlọ́de àríyá, ẹ̀kọ́ àti àwọn mìíràn tó fara pẹ́ ẹ. Bẹ́ẹ̀ ni òfin ìbòmú bojú wà síbẹ̀.
Gómìnà Fáyemí dẹkùn un òfin èèyàn ìlú ẹ gbélé,láti aago mẹ́fà idaji sí aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ bẹ̀rẹ̀ l'ọ́jọ́ Ajé 27,oṣù kẹrin sí Àìkú ọ́jọ́ kẹta, Oṣù karùn ún ọdún 2020. Bẹ́ẹ̀ lòfin fààyè gba àwọn òṣìṣẹ́ tí iṣẹ́ wọ́n pọn dandan mọ́ ń tí a ń ṣọ yìí.
Gómìnà Fáyemí ní, káràkátà o máa wáyé láàrin ọjọ́ mẹ́ta péré láàrin aago méje àárọ sí mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ lọjọ Ajé sí Ọjọ́rùú láti fààyè gba àwọn orí ò rù,ẹnu ò jẹ.
Kò ṣàì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lásìkò tó ń bá àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà ṣọ̀rọ̀ , oye òǹkà èèyàn mẹ́rin sí mẹ́jọ tí àrùn apinni léèmí náà ti farahàn, nigba tí àwọn márùn ún n gbà ìtọ́jú.
Ó ṣọ ọ́ yanya pé, àṣẹ kí káràkátà ó dúró wápe t'íjọba pa láwọn ọjà ńlá ńlá kárí ìlú, ò yípadà.
Ó ní, kò ní sí pípa fẹẹ ọkọ̀ láti ìlú mìíràn sì tí ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ló pàrọwà sáwọn onímọ́tò ati márúwá láti tẹ̀lé Ìlànà tí Ìjọba làálẹ̀ kí wọ́n má baà rí ojúpọ́n ìjọba.
Ó kádíì ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, àwọn òṣìṣẹ́ láti àkàsọ̀ kẹtàlá sókè yóó padà wọlé fún àkànṣe iṣẹ́ ìlú níbàámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ lásìkò .
.
Comments
Post a Comment