Eeyan Keji Ku Nitori Korona l'Ọ̀yọ́


Fẹ́mi Akínṣọlá

Ikú kìí se ẹgbẹ́ àrùn o. Àrùn ló se é wò,a ò rí ti  ọlọ́jọ́ se.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́  ti kéde pé ó ti di ẹni méjì tó kú báyìí nítorí àrùn apinni léèmí Coronavirus ní ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ , onímọ Ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé  ló kéde rẹ̀ lórí ẹ̀rọ  ìkànnì abẹ́yefò Twitter ní Ọjọ́ Àìkú.

Gómìnà náà ní ẹni tókú náà wà lára àwọn tí àyẹ̀wò ṣẹṣẹ fihàn pé wọ́n ní àrùn apinni léèmí Coronavirus.

Bẹ́ẹ̀ ni Gómìnà náà fikún un pé ènìyàn mọ́kànlélógún ló ti ní àrùn náà nípìńlẹ̀ náà, àmọ́ ènìyàn mẹ́jọ nínú wọn ló ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́.

Comments