Buhari Salaye Oun ti yio fi ọgbọ̀n bílíọ̀nù dọ́là owóyàá àjọ IMF ṣe
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ijọba àpapọ̀ ti ṣàlàyé pe, oun fẹ́ gba owó lowo ajo IMF láti mú kí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà gbéra lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Covid-19 yìí, nitori pe epo rọ̀bì kò tà mọ́ ní ọjà àgbáyé, bee si ni ọ̀rọ̀ ajé àgbáyé ti dẹnu kọlẹ̀.
Ìjọba ní owó náà ni òun fẹ́ fi ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ tó yà kalẹ̀ nínú ètò ìṣúná ọdún 2020.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun nílé aṣòfin àpapọ̀ ilẹ̀ wa fi òǹtẹ̀ lu ọgbọ̀n bílíọ̀nù dọ́là ($30bn) owó tí Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ wá fẹ́ gbà lọ́dọ̀ àjọ ayánilówó lágbàáyé IMF.
Láti ìgbà tí ìjọba àpapọ̀ sì ti tẹ́ pẹpẹ owóyàá náà síwájú àwọn aṣòfin àgbà, làwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí tí ń béèrè pé, ṣé ilẹ̀ wá tún nílò owóyàá kankan lásìkò tí ọrọ̀ ajé àgbáyé ti dagun yìí?
Wọ́n ní ṣé àkọ̀tun ìbéèrè fún owóyàá yìí, èyí tí yóò mú kí gbèsè tí ilẹ̀ wá jẹ láwùjọ àgbáyé fò fẹ̀rẹ̀ sì bílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn ($97bn), kò ní ṣe àkóbá ńlá fún ìgbáyé-gbádùn àti ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí?

Comments
Post a Comment