Bi Olórí ẹ̀ṣọ́ Tinubu se kú iku àrùn Coronavirus
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ikú pabírí, abírí kú, ikú pa àlàárì, ikú pa sányán baba aṣọ. Ikú kò mọ ọ̀lẹ ,bẹ́ẹ̀ ni kò wojú alágbára, ló díá fún bó ṣé síwọ́ lu olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò fún adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu,Alhaji Lateef Raheem tó kù lẹ́yìn tó lùgbàdì àrùn apinni léèmí Coronavirus.
Tinubu fi ọ̀rọ̀ ẹ kú ara fẹ́rakù yìí léde nínú àtẹ̀jáde tí ikọ̀ ìròyìn adarí náà buwọ́lù.
Nínú àtẹ̀jáde náà ni Tinubu ti fi léde wí pé òun àti ìyàwó òun kò ní àrùn apinni léèmí Coronavirus lẹ́yìn tí àwọn ṣe àyẹ̀wò.
Adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ní àwọn gbé ìgbésẹ̀ láti se àyẹ̀wò náà kété tí àyẹ̀wò fi léde pé àrùn apinni léèmí Coronavirus ló pa Alhaji Raheem.
Àmọ́ wọ́n ní ọ̀kan nínú àwọn olùrànlọ́wọ́ fún Bola Tinubu ti lùgbàdì àrùn náà tó sì ti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀.
Wọ́n fikún un pé Àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà,NCDC ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá àwọn tí wọ́n ti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú olóògbé náà fún àyẹ̀wò árùn Coronavirus.
Ogójì ènìyàn ló ti kú lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ìgbà tí àrùn Coronavirus náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jà ràn-ìn ní Nàìjíríà.
Comments
Post a Comment